Categories
JẸNẸSISI

JẸNẸSISI Ọ̀rọ̀ Iṣaaju

Ọ̀rọ̀ Iṣaaju

Ìtumọ̀

Jẹnẹsisi

ni “Ìpìlẹ̀” tabi “Ìṣẹ̀dálẹ̀.” Inú ìwé Jẹnẹsisi ni ìtàn ìṣẹ̀dálẹ̀ ayé wà; bí a ti ṣẹ̀dá ọmọ eniyan, ìpìlẹ̀ ẹ̀ṣẹ̀ ati bí ìnira ṣe bẹ̀rẹ̀ láyé, ati ìhà tí Ọlọrun kọ sí eniyan. Ọ̀nà meji pataki ni a lè pín ìtàn inú ìwé Jẹnẹsisi sí:

(1)

Orí 1-11

: Ìtàn nípa ìṣẹ̀dálẹ̀ ayé ati ìtàn ìpìlẹ̀ àwọn ẹ̀yà eniyan. Bákan náà, ní ẹ̀kúnrẹ́rẹ́ a óo rí kà nípa Adamu ati Efa, Kaini ati Abeli, Noa ati ìkún omi, ati nípa ilé ìṣọ́ Babiloni.

(2)

Orí 12-50

: Ìtàn àwọn Baba ńlá àwọn ọmọ Israẹli. Abrahamu ni ẹni àkọ́kọ́, ó jẹ́ olókìkí eniyan nípa ẹ̀mí igbagbọ tí ó ní, ati ìgbọràn sí Ọlọrun. Ìtàn ọmọ rẹ̀, Isaaki, ni ó tẹ̀lé e, lẹ́yìn náà ni ti ọmọ ọmọ rẹ̀, Jakọbu, (tí ó tún ń jẹ́ Israẹli), ati ti àwọn ọmọ Jakọbu mejeejila, àwọn ni wọ́n pilẹ̀ àwọn ẹ̀yà Israẹli mejeejila. Ní pataki, ìtàn Josẹfu, ọ̀kan ninu àwọn ọmọ Israẹli jẹyọ ati ìṣẹ̀lẹ̀ tí ó ṣe okùnfà bí Jakọbu ati àwọn ọmọ rẹ̀ pẹlu àwọn ẹbí wọn ṣe di èrò Ijipti, (ní ilẹ̀ tí wọ́n ti ṣe àtìpó).

Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé ìwé yìí sọ ọpọlọpọ ìtàn nípa eniyan, sibẹ ohun tí Ọlọrun ṣe ni ó pilẹ̀ rẹ̀, tí ó sì jẹ́ kókó pataki. Ní ìbẹ̀rẹ̀ ìwé náà, a rí ẹ̀rí ìdánilójú pé Ọlọrun ni ó dá ayé, ní ìkẹyìn, Ọlọrun ṣèlérí pé òun yóo máa fi ìfẹ́ hàn sí àwọn eniyan òun. Láti ìbẹ̀rẹ̀ dé òpin ìwé náà, Ọlọrun ni ẹ̀dá ìtàn tí ó súyọ jùlọ, òun ni onídàájọ́, a sì máa fi ìyà jẹ ẹni tí ó bá dẹ́ṣẹ̀, a máa darí àwọn eniyan rẹ̀, a sì máa ràn wọ́n lọ́wọ́, bákan náà ni ó máa ń ṣàkóso ìgbésí ayé wọn. A kọ ìwé àtayébáyé yìí láti ṣe àgbékalẹ̀ ìtàn nípa igbagbọ àwọn eniyan kan ati pé kí iná irú igbagbọ bẹ́ẹ̀ baà lè máa jó àjóròkè sí i.

Àwọn Ohun tí ó wà ninu Ìwé yìí ní Ìsọ̀rí-ìsọ̀rí

Ìtàn ìṣẹ̀dálẹ̀ ayé ati ti ìpìlẹ̀ àwọn ẹ̀yà eniyan 1:1–2:25

Ìpìlẹ̀ ẹ̀ṣẹ̀ ati ìjìyà 3:1-24

Ìtàn láti orí Adamu títí dé ti Noa 4:1–5:32

Noa ati ìkún omi 6:1–10:32

Ilé ìṣọ́ Babiloni 11:1-9

Ìtàn láti orí Ṣemu títí dé ti Abramu 11:10-32

Àwọn Baba ńlá àwọn ọmọ Israẹli: Abrahamu, Isaaki, Jakọbu 12:1–35:29

Àwọn arọmọdọmọ Esau 36:1-43

Josẹfu ati àwọn arakunrin rẹ̀ 37:1–45:28

Àwọn ẹ̀yà Israẹli ní ilẹ̀ Ijipti 46:1–50:26

Categories
JẸNẸSISI

JẸNẸSISI 1

Ìtàn Bí A ṣe Dá Ayé

1 Ní ìbẹ̀rẹ̀, nígbà tí Ọlọrun dá ọ̀run ati ayé,

2 ayé rí júujùu, ó sì ṣófo. Ibú omi bo gbogbo ayé, gbogbo rẹ̀ ṣókùnkùn biribiri, ẹ̀mí Ọlọrun sì ń rábàbà lójú omi.

3 Ọlọrun pàṣẹ pé kí ìmọ́lẹ̀ wà, ìmọ́lẹ̀ sì wà.

4 Ọlọrun wò ó, ó rí i pé ìmọ́lẹ̀ náà dára, ó sì yà á kúrò lára òkùnkùn.

5 Ó sọ ìmọ́lẹ̀ ní ọ̀sán, ó sì sọ òkùnkùn ní òru. Ilẹ̀ ṣú, ilẹ̀ sì tún mọ́, ó di ọjọ́ kinni.

6 Ọlọrun pàṣẹ pé kí awọsanma wà láàrin omi, kí ó pín omi sí ọ̀nà meji, kí ó sì jẹ́ ààlà láàrin omi tí ó wà lókè awọsanma náà ati èyí tí ó wà ní ìsàlẹ̀ rẹ̀.

7 Ọlọrun dá awọsanma, ó fi ya omi tí ó wà lábẹ́ rẹ̀ kúrò lára èyí tí ó wà lókè rẹ̀, ó sì rí bẹ́ẹ̀.

8 Ọlọrun sọ awọsanma náà ní ojú ọ̀run. Ilẹ̀ ṣú, ilẹ̀ sì tún mọ́, ó di ọjọ́ keji.

9 Ọlọrun pàṣẹ pé kí omi tí ó wà lábẹ́ ọ̀run wọ́jọ pọ̀ sí ojú kan, kí ìyàngbẹ ilẹ̀ lè farahàn, ó sì rí bẹ́ẹ̀.

10 Ó sọ ìyàngbẹ ilẹ̀ náà ní ilẹ̀, ó sì sọ omi tí ó wọ́jọ pọ̀ ní òkun. Ó wò ó, ó sì rí i pé ó dára.

11 Ọlọrun pàṣẹ pé kí ilẹ̀ hu koríko jáde oríṣìíríṣìí ohun ọ̀gbìn ati ewéko tí ń so ati oríṣìíríṣìí igi eléso tí ń so èso tí ó ní irúgbìn ninu, ó sì rí bẹ́ẹ̀.

12 Ilẹ̀ bá hu koríko jáde, oríṣìíríṣìí ohun ọ̀gbìn ati ewéko tí ń so ati oríṣìíríṣìí igi eléso tí ó ní irúgbìn ninu. Ọlọrun wò wọ́n, ó sì rí i pé wọ́n dára.

13 Ilẹ̀ ṣú, ilẹ̀ sì tún mọ́, ó di ọjọ́ kẹta.

14 Ọlọrun pàṣẹ pé kí àwọn ìmọ́lẹ̀ wà ní ojú ọ̀run, láti fi ààlà sí ààrin ọ̀sán ati òru, kí wọ́n wà láti jẹ́ àmì, ati láti máa fi àkókò àjọ̀dún, ọjọ́, ati ọdún hàn,

15 kí wọ́n sì jẹ́ ìmọ́lẹ̀ ní ojú ọ̀run láti máa tàn sórí ilẹ̀ ayé, ó sì rí bẹ́ẹ̀.

16 Ọlọrun dá ìmọ́lẹ̀ ńlá meji: ó dá oòrùn láti máa jọba ọ̀sán, ati òṣùpá láti máa jọba òru, ó sì dá àwọn ìràwọ̀ pẹlu.

17 Ọlọrun fi wọ́n sí ojú ọ̀run láti máa tan ìmọ́lẹ̀ sórí ilẹ̀ ayé,

18 láti máa jọba lórí ọ̀sán ati òru, ati láti fi ààlà sí ààrin ìmọ́lẹ̀ ati òkùnkùn. Ọlọrun wò wọ́n, ó sì rí i pé wọ́n dára.

19 Ilẹ̀ ṣú, ilẹ̀ sì tún mọ́, ó di ọjọ́ kẹrin.

20 Ọlọrun pàṣẹ pé kí omi kún fún oríṣìíríṣìí ẹ̀dá alààyè, kí ojú ọ̀run sì kún fún àwọn ẹyẹ.

21 Ó dá àwọn ẹranko ńláńlá inú omi ati oríṣìíríṣìí ẹ̀dá alààyè tí ń gbé inú omi, ati oríṣìíríṣìí ẹyẹ. Ọlọrun wò wọ́n, ó sì rí i pé wọ́n dára.

22 Ọlọrun súre fún wọn, ó ní, “Ẹ máa bímọ lémọ, kí ẹ sì máa pọ̀ sí i, kí ẹ kún gbogbo inú omi òkun, kí àwọn ẹyẹ náà sì máa pọ̀ sí i lórí ilẹ̀.”

23 Ilẹ̀ ṣú, ilẹ̀ sì tún mọ́, ó di ọjọ́ karun-un.

24 Ọlọrun pàṣẹ pé kí ilẹ̀ mú oríṣìíríṣìí ẹ̀dá alààyè jáde: oríṣìíríṣìí ẹran ọ̀sìn, oríṣìíríṣìí ohun tí ń fàyà fà lórí ilẹ̀ ati oríṣìíríṣìí ẹranko ìgbẹ́, ó sì rí bẹ́ẹ̀.

25 Bẹ́ẹ̀ ni Ọlọrun dá gbogbo wọn, ó wò wọ́n, ó sì rí i pé wọ́n dára.

26 Lẹ́yìn náà Ọlọrun wí pé, “Ẹ jẹ́ kí á dá eniyan ní àwòrán ara wa, kí ó rí bíi wa, kí wọ́n ní àṣẹ lórí àwọn ẹja inú òkun, ẹyẹ ojú ọ̀run, àwọn ẹranko ati lórí gbogbo ayé ati àwọn ohun tí wọn ń fàyà fà lórí ilẹ̀.”

27 Bẹ́ẹ̀ ni Ọlọrun dá eniyan ní àwòrán ara rẹ̀. Takọ-tabo ni ó dá wọn.

28 Ó súre fún wọn, ó ní, “Ẹ máa bímọ lémọ, kí ẹ máa pọ̀ sí i, kí ẹ kún gbogbo ayé. Kí ayé wà ní ìkáwọ́ yín, kí ẹ ní àṣẹ lórí àwọn ẹja inú omi, lórí ẹyẹ ojú ọ̀run, ati lórí gbogbo ẹ̀dá alààyè tí ń rìn káàkiri lórí ilẹ̀ ayé.”

29 Ọlọrun tún wí pé, “Mo ti pèsè gbogbo ohun ọ̀gbìn tí ń so èso ati igi tí ń so èso tí ó ní irúgbìn ninu fún yín láti jẹ.

30 Bẹ́ẹ̀ ni mo sì ti pèsè àwọn ewéko fún oúnjẹ àwọn ẹranko, ati àwọn ẹyẹ, ati àwọn ohun tí ń fàyà fà lórí ilẹ̀, ati gbogbo ẹ̀dá alààyè.” Ó sì rí bẹ́ẹ̀.

31 Ọlọrun wo gbogbo ohun tí ó dá, ó sì rí i pé wọ́n dára. Ilẹ̀ ṣú, ilẹ̀ sì tún mọ́, ó di ọjọ́ kẹfa.

Categories
JẸNẸSISI

JẸNẸSISI 2

1 Bẹ́ẹ̀ ni Ọlọrun ṣe parí dídá ọ̀run ati ayé, ati gbogbo ohun tí ó wà ninu wọn.

2 Ní ọjọ́ keje, Ọlọrun parí iṣẹ́ ìṣẹ̀dá tí ó ti ń ṣe, ó sì sinmi ní ọjọ́ náà.

3 Ó súre fún ọjọ́ keje yìí, ó sì yà á sí mímọ́, nítorí pé ọjọ́ náà ni ó sinmi ninu gbogbo iṣẹ́ ìṣẹ̀dá tí ó ti ń ṣe bọ̀.

4 Bẹ́ẹ̀ ni Ọlọrun ṣe dá ọ̀run ati ayé.

Ọgbà Edẹni

Nígbà tí OLUWA Ọlọrun dá ọ̀run ati ayé,

5 kò tíì sí ohun ọ̀gbìn kankan lórí ilẹ̀, bẹ́ẹ̀ ni ewéko kankan kò tíì hù jáde nítorí pé OLUWA Ọlọrun kò tíì rọ òjò sórí ilẹ̀, kò sì tíì sí eniyan láyé tí yóo máa ro ilẹ̀.

6 Ṣugbọn omi kan a máa ru jáde láti inú ilẹ̀ láti mú kí gbogbo ilẹ̀ rin.

7 Nígbà náà ni OLUWA Ọlọrun bù ninu erùpẹ̀ ilẹ̀, ó fi mọ eniyan. Ó mí èémí ìyè sí ihò imú rẹ̀, eniyan sì di ẹ̀dá alààyè.

8 OLUWA Ọlọrun ṣe ọgbà kan sí Edẹni, ní ìhà ìlà oòrùn, ó fi eniyan tí ó mọ sinu rẹ̀.

9 Láti inú ilẹ̀ ni OLUWA Ọlọrun ti mú kí oríṣìíríṣìí igi hù jáde ninu ọgbà náà, tí wọ́n dùn ún wò, tí wọ́n sì dára fún jíjẹ. Igi ìyè wà láàrin ọgbà náà, ati igi ìmọ̀ ibi ati ire.

10 Odò kan ṣàn jáde láti inú ọgbà Edẹni tí omi rẹ̀ máa ń mú kí ọgbà náà rin. Lẹ́yìn tí odò yìí ṣàn kọjá ọgbà Edẹni, ó pín sí mẹrin.

11 Orúkọ odò kinni ni Piṣoni. Òun ni ó ṣàn yí gbogbo ilẹ̀ Hafila ká, níbi tí wúrà wà.

12 Wúrà ilẹ̀ náà dára. Turari olówó iyebíye tí wọ́n ń pè ní bedeliumu, ati òkúta olówó iyebíye tí wọ́n ń pè ní onikisi wà níbẹ̀ pẹlu.

13 Orúkọ odò keji ni Gihoni, òun ni ó ṣàn yí gbogbo ilẹ̀ Kuṣi ká.

14 Orúkọ odò kẹta ni Tigirisi, òun ni ó ṣàn lọ sí apá ìlà oòrùn Asiria. Ẹkẹrin ni odò Yufurate.

15 OLUWA Ọlọrun fi ọkunrin tí ó dá sinu ọgbà Edẹni, kí ó máa ro ó, kí ó sì máa tọ́jú rẹ̀.

16 Ó pàṣẹ fún ọkunrin náà, ó ní, “O lè jẹ ninu èso gbogbo igi tí ó wà ninu ọgbà yìí,

17 ṣugbọn o kò gbọdọ̀ jẹ ninu èso igi ìmọ̀ ibi ati ire. Ọjọ́ tí o bá jẹ ẹ́ ni o óo kú.”

18 Lẹ́yìn náà OLUWA Ọlọrun sọ pé, “Kò dára kí ọkunrin náà nìkan dá wà, n óo ṣe olùrànlọ́wọ́ kan fún un, tí yóo dàbí rẹ̀.”

19 Nítorí náà, OLUWA Ọlọrun bu erùpẹ̀ ilẹ̀, ó fi mọ gbogbo ẹranko ati gbogbo ẹyẹ. Ó kó wọn tọ ọkunrin náà wá, láti mọ orúkọ tí yóo sọ olukuluku wọn. Orúkọ tí ó sì sọ wọ́n ni wọ́n ń jẹ́.

20 Bẹ́ẹ̀ ni ọkunrin náà sọ gbogbo ẹran ọ̀sìn ati gbogbo ẹyẹ ati ẹranko ní orúkọ, ṣugbọn ninu gbogbo wọn, kò sí ọ̀kan tí ó le jẹ́ olùrànlọ́wọ́ tí ó yẹ ẹ́.

21 Nígbà náà OLUWA Ọlọrun kun ọkunrin yìí ní oorun àsùnwọra, nígbà tí ó sùn, Ọlọrun yọ ọ̀kan ninu àwọn egungun ìhà rẹ̀, ó sì fi ẹran dípò rẹ̀.

22 Ó fi egungun náà mọ obinrin kan, ó sì mú un tọ ọkunrin náà lọ.

23 Ọkunrin náà bá wí pé,

“Mo ṣẹ̀ṣẹ̀ rí ẹni tí ó dàbí mi,

ẹni tí a mú jáde láti inú egungun ati ẹran ara mi;

obinrin ni yóo máa jẹ́,

nítorí pé láti ara ọkunrin ni a ti mú un jáde.”

24 Ìdí nìyí tí ọkunrin yóo ṣe fi baba ati ìyá rẹ̀ sílẹ̀, tí yóo sì faramọ́ aya rẹ̀, àwọn mejeeji yóo sì di ara kan ṣoṣo.

25 Ọkunrin náà ati obinrin náà wà ní ìhòòhò, ojú kò sì tì wọ́n.

Categories
JẸNẸSISI

JẸNẸSISI 3

Ìwà Àìgbọràn

1 Ejò jẹ́ alárèékérekè ju gbogbo ẹranko tí OLUWA Ọlọrun dá lọ. Ejò bi obinrin náà pé, “Ngbọ́! Ṣé nítòótọ́ ni Ọlọrun sọ pé ẹ kò gbọdọ̀ jẹ ninu èso àwọn igi ọgbà yìí?”

2 Obinrin náà dá a lóhùn, ó ní: “A lè jẹ ninu èso àwọn igi tí wọ́n wà ninu ọgbà,

3 àfi igi tí ó wà láàrin ọgbà nìkan ni Ọlọrun ní a kò gbọdọ̀ jẹ ninu èso rẹ̀, a kò tilẹ̀ gbọdọ̀ fọwọ́ kàn án, ati pé ọjọ́ tí a bá fọwọ́ kàn án ni a óo kú.”

4 Ṣugbọn ejò náà dáhùn, ó ní, “Ẹ kò ní kú rárá,

5 Ọlọrun sọ bẹ́ẹ̀ nítorí ó mọ̀ pé bí ẹ bá jẹ ẹ́, ojú yín yóo là, ẹ óo sì dàbí òun alára, ẹ óo mọ ire yàtọ̀ sí ibi.”

6 Nígbà tí obinrin yìí ṣe akiyesi pé èso igi náà dára fún jíjẹ ati pé ó dùn ún wò, ó sì wòye bí yóo ti dára tó láti jẹ́ ọlọ́gbọ́n, ó mú ninu èso igi náà, ó jẹ ẹ́. Lẹ́yìn náà, ó fún ọkọ rẹ̀, ọkọ rẹ̀ náà sì jẹ ẹ́.

7 Ojú àwọn mejeeji bá là, wọ́n sì mọ̀ pé ìhòòhò ni àwọn wà, wọ́n bá gán ewé ọ̀pọ̀tọ́ pọ̀, wọ́n sán an mọ́ ìdí.

8 Nígbà tí ó di ìrọ̀lẹ́, wọ́n gbúròó OLUWA Ọlọrun tí ń rìn ninu ọgbà. Wọ́n bá sá pamọ́ sí ààrin àwọn igi ọgbà.

9 Ṣugbọn OLUWA Ọlọrun pe ọkunrin náà, ó bi í pé, “Níbo ni o wà?”

10 Ó dá Ọlọrun lóhùn, ó ní, “Nígbà tí mo gbúròó rẹ ninu ọgbà, ẹ̀rù bà mí, mo bá farapamọ́ nítorí pé ìhòòhò ni mo wà.”

11 Ọlọrun bi í pé, “Ta ló sọ fún ọ pé ìhòòhò ni o wà? Àbí o ti jẹ ninu èso igi tí mo pàṣẹ fún ọ pé o kò gbọdọ̀ jẹ?”

12 Ọkunrin náà dáhùn, ó ní, “Obinrin tí o fi tì mí ni ó fún mi ninu èso igi náà, mo sì jẹ ẹ́.”

13 OLUWA Ọlọrun bi obinrin náà pé, “Irú kí ni o dánwò yìí?” Obinrin náà dáhùn, ó ní, “Ejò ni ó tàn mí tí mo fi jẹ ẹ́.”

Ọlọrun Ṣèdájọ́

14 OLUWA Ọlọrun bá sọ fún ejò náà pé,

“Nítorí ohun tí o ṣe yìí,

o di ẹni ìfibú jùlọ láàrin gbogbo àwọn ẹran ọ̀sìn ati àwọn ẹranko.

Àyà rẹ ni o óo máa fi wọ́ káàkiri,

erùpẹ̀ ni o óo sì máa jẹ ní gbogbo ọjọ́ ayé rẹ.

15 N óo dá ọ̀tá sí ààrin ìwọ ati obinrin náà,

ati sí ààrin atọmọdọmọ rẹ ati atọmọdọmọ rẹ̀.

Wọn óo máa fọ́ ọ lórí,

ìwọ náà óo sì máa bù wọ́n ní gìgísẹ̀ jẹ.”

16 Lẹ́yìn náà Ọlọrun wí fún obinrin náà pé,

“N óo fi kún ìnira rẹ nígbà tí o bá lóyún,

ninu ìrora ni o óo máa bímọ.

Sibẹsibẹ, lọ́dọ̀ ọkọ rẹ ni ìfẹ́ rẹ yóo máa fà sí,

òun ni yóo sì máa ṣe olórí rẹ.”

17 Ó sọ fún Adamu, pé,

“Nítorí pé o gba ohun tí aya rẹ wí fún ọ,

o sì jẹ ninu èso igi tí mo pàṣẹ fún ọ pé o kò gbọdọ̀ jẹ,

mo fi ilẹ̀ gégùn-ún títí lae nítorí rẹ.

Pẹlu ìnira ni o óo máa mú oúnjẹ jáde láti inú ilẹ̀ ní gbogbo ọjọ́ ayé rẹ.

18 Ẹ̀gún ati òṣùṣú ni ilẹ̀ yóo máa hù jáde fún ọ,

ewéko ni o óo sì máa jẹ.

19 Iṣẹ́ àṣelàágùn ni o óo máa ṣe, kí o tó rí oúnjẹ jẹ,

títí tí o óo fi pada sí ilẹ̀,

nítorí inú rẹ̀ ni a ti mú ọ wá.

Erùpẹ̀ ni ọ́,

o óo sì pada di erùpẹ̀.”

20 Adamu sọ iyawo rẹ̀ ní Efa, nítorí pé òun ni ìyá gbogbo eniyan.

21 OLUWA Ọlọrun fi awọ ẹranko rán aṣọ fún Adamu ati iyawo rẹ̀, ó sì fi wọ̀ wọ́n.

Ọlọrun Lé Adamu ati Efa jáde ninu Ọgbà

22 Lẹ́yìn náà, OLUWA Ọlọrun wí pé, “Nisinsinyii tí ọkunrin náà ti dàbí wa, tí ó sì ti mọ ire yàtọ̀ sí ibi, kí ó má lọ mú ninu èso igi ìyè, kí ó jẹ ẹ́, kí ó sì wà láàyè títí lae.”

23 Nítorí náà OLUWA Ọlọrun lé e jáde kúrò ninu ọgbà Edẹni, kí ó lọ máa ro ilẹ̀, ninu èyí tí Ọlọrun ti mú un jáde.

24 Ó lé e jáde, ó sì fi Kerubu kan sí ìhà ìlà oòrùn ọgbà náà láti máa ṣọ́ ọ̀nà tí ó lọ sí ibi igi ìyè náà, pẹlu idà oníná tí ń jò bùlà bùlà, tí ó sì ń yí síhìn-ín sọ́hùn-ún.

Categories
JẸNẸSISI

JẸNẸSISI 4

Kaini ati Abeli

1 Nígbà tí ó yá, Adamu bá Efa, aya rẹ̀, lòpọ̀, ó lóyún, ó sì bí ọmọkunrin kan. Ó ní, “Pẹlu ìrànlọ́wọ́ OLUWA, mo ní ọmọkunrin kan,” ó sọ ọmọ náà ní Kaini.

2 Lẹ́yìn náà, ó bí ọmọkunrin mìíràn, ó sọ ọ́ ní Abeli. Iṣẹ́ darandaran ni Abeli ń ṣe, Kaini sì jẹ́ àgbẹ̀.

3 Nígbà tí ó yá, Kaini mú ninu èso oko rẹ̀, ó fi rúbọ sí OLUWA.

4 Abeli náà mú àkọ́bí ọ̀kan ninu àwọn aguntan rẹ̀, ó pa á, ó sì fi ibi tí ó lọ́ràá, tí ó dára jùlọ lára rẹ̀ rúbọ sí OLUWA. Inú OLUWA dùn sí Abeli, ó sì gba ẹbọ rẹ̀,

5 ṣugbọn inú Ọlọrun kò dùn sí Kaini, kò sì gba ẹbọ rẹ̀. Inú bí Kaini, ó sì fa ojú ro.

6 OLUWA bá bi Kaini, ó ní, “Kí ló dé tí ò ń bínú, tí o sì fa ojú ro?

7 Bó bá jẹ́ pé o ṣe rere ni, ara rẹ ìbá yá gágá, ẹbọ rẹ yóo sì jẹ́ ìtẹ́wọ́gbà. Ṣugbọn nítorí pé ibi ni o ṣe, ẹ̀ṣẹ̀ ba dè ọ́ lẹ́nu ọ̀nà rẹ, ó fẹ́ jọba lé ọ lórí ṣugbọn tìrẹ ni láti ṣẹgun rẹ̀.”

8 Nígbà tí ó yá, Kaini pe Abeli lọ sinu oko. Nígbà tí wọ́n wà níbẹ̀, Kaini dìde sí Abeli àbúrò rẹ̀, ó sì lù ú pa.

9 OLUWA bá pe Kaini, ó bi í pé, “Níbo ni Abeli, àbúrò rẹ wà?” Ó dáhùn, ó ní, “N kò mọ̀. Ṣé èmi wá jẹ́ bí olùṣọ́ àbúrò mi ni?”

10 OLUWA bá bi í pé “Kí ni o dánwò yìí? Láti inú ilẹ̀ ni ẹ̀jẹ̀ àbúrò rẹ ti ń kígbe pè mí.

11 Wò ó! mo fi ọ́ gégùn-ún lórí ilẹ̀ tí ó mu ẹ̀jẹ̀ arakunrin rẹ tí o pa.

12 Láti òní lọ, nígbà tí o bá dá oko, ilẹ̀ kò ní fi gbogbo agbára rẹ̀ so èso fún ọ mọ́, ìsáǹsá ati alárìnká ni o óo sì jẹ́ lórí ilẹ̀ ayé.”

13 Kaini dá OLUWA lóhùn, ó ní, “Ìjìyà yìí ti pọ̀jù fún mi.

14 O lé mi kúrò lórí ilẹ̀, ati kúrò níwájú rẹ, n óo sì di ìsáǹsá ati alárìnká lórí ilẹ̀ ayé, nígbà tí ó bá yá, ẹnikẹ́ni tí ó bá rí mi ni yóo pa mí.”

15 Ṣugbọn OLUWA dáhùn, ó ní, “Rárá o! ẹnikẹ́ni tí ó bá pa Kaini, a óo gbẹ̀san lára rẹ̀ nígbà meje.” Nítorí náà OLUWA fi àmì sí ara Kaini kí ẹnikẹ́ni tí ó bá rí i má baà pa á.

16 Kaini bá kúrò níwájú OLUWA, ó lọ ń gbé ìlú tí ń jẹ́ Nodu.Ó wà ní apá ìlà oòrùn ọgbà Edẹni.

Àwọn Ìran Kaini

17 Kaini bá aya rẹ̀ lòpọ̀, ó lóyún, ó sì bí Enọku. Kaini lọ tẹ ìlú kan dó, ó sọ ìlú náà ní Enọku, tí í ṣe orúkọ ọmọ rẹ̀.

18 Enọku bí ọmọkunrin kan, ó sọ ọ́ ní Iradi. Iradi bí Mehujaeli, Mehujaeli bí Metuṣaeli, Metuṣaeli bí Lamẹki.

19 Lamẹki fẹ́ iyawo meji, ọ̀kan ń jẹ́ Ada, ekeji ń jẹ́ Sila.

20 Ada ni ó bí Jabali, tíí ṣe baba ńlá gbogbo àwọn tí wọn ń gbé inú àgọ́, tí wọ́n sì ń sin ẹran ọ̀sìn.

21 Orúkọ arakunrin rẹ̀ ni Jubali, òun ni baba ńlá gbogbo àwọn tí wọn ń lu hapu ati àwọn tí wọn ń fọn fèrè.

22 Sila bí Tubali Kaini. Tubali Kaini yìí ni baba ńlá gbogbo àwọn alágbẹ̀dẹ tí ń rọ ohun èlò irin, ati idẹ. Arabinrin Tubali Kaini ni Naama.

23 Nígbà tí ó yá Lamẹki pe àwọn aya rẹ̀, ó ní:

“Ada ati Sila, ẹ tẹ́tí sílẹ̀,

ẹ̀yin aya mi, ẹ gbọ́ mi ní àgbọ́yé:

Mo pa ọkunrin kan nítorí pé ó pa mí lára,

mo gba ẹ̀mí eniyan nítorí pé ó ṣá mi lọ́gbẹ́.

24 Bí ẹ̀san ti Kaini bá jẹ́ ẹ̀mí eniyan meje,

ẹ̀san ti Lamẹki gbọdọ̀ jẹ́ aadọrin ẹ̀mí ó lé meje.”

Seti ati Enọṣi

25 Adamu tún bá aya rẹ̀ lòpọ̀, ó lóyún, ó sì bí ọmọkunrin kan. Ó sọ ọ́ ní Seti, ó ní: “Ọlọrun tún fún mi ní ọmọ mìíràn dípò Abeli tí Kaini pa.”

26 Seti bí ọmọkunrin kan, ó sọ ọ́ ní Enọṣi. Nígbà náà ni àwọn eniyan bẹ̀rẹ̀ sí jọ́sìn ní orúkọ mímọ́ OLUWA.

Categories
JẸNẸSISI

JẸNẸSISI 5

Ìwé Àkọsílẹ̀ Ìran Adamu

1 Àkọsílẹ̀ ìran Adamu nìyí: Nígbà tí Ọlọrun dá eniyan, ó dá wọn ní àwòrán ara rẹ̀.

2 Takọ-tabo ni ó dá wọn, ó súre fún wọn, ó sì sọ wọ́n ní eniyan.

3 Nígbà tí Adamu di ẹni aadoje (130) ọdún, ó bí ọmọkunrin kan. Ọmọ náà jọ ọ́ gidigidi, bí Adamu ti rí gan-an ni ọmọ náà rí. Ó bá sọ ọ́ ní Seti.

4 Lẹ́yìn tí ó bí Seti, ó tún gbé ẹgbẹrin (800) ọdún láyé, ó sì bí àwọn ọmọ mìíràn lọkunrin ati lobinrin.

5 Gbogbo ọdún tí Adamu gbé láyé jẹ́ ẹẹdẹgbẹrun ọdún ó lé ọgbọ̀n (930), kí ó tó kú.

6 Nígbà tí Seti di ẹni ọdún marundinlaadọfa (105), ó bí Enọṣi.

7 Lẹ́yìn tí ó bí Enọṣi, ó tún gbé ẹgbẹrin ọdún ó lé meje (807) láyé, ó sì bí àwọn ọmọ mìíràn lọkunrin ati lobinrin.

8 Gbogbo ọdún tí Seti gbé láyé jẹ́ ẹẹdẹgbẹrun ọdún ó lé mejila (912), kí ó tó kú.

9 Nígbà tí Enọṣi di ẹni aadọrun-un ọdún, ó bí Kenani.

10 Lẹ́yìn tí ó bí Kenani, ó gbé ẹgbẹrin ọdún ó lé mẹẹdogun (815) láyé, ó sì bí àwọn ọmọ mìíràn lọkunrin ati lobinrin.

11 Gbogbo ọdún tí Enọṣi gbé láyé jẹ́ ẹẹdẹgbẹrun ọdún ó lé marun-un (905) kí ó tó kú.

12 Nígbà tí Kenani di ẹni aadọrin ọdún, ó bí Mahalaleli.

13 Lẹ́yìn tí ó bí Mahalaleli, ó gbé ẹgbẹrin ọdún ó lé ogoji (840) láyé, ó sì bí àwọn ọmọ mìíràn lọkunrin ati lobinrin.

14 Gbogbo ọdún tí Kenani gbé láyé jẹ́ ẹẹdẹgbẹrun ọdún ó lé mẹ́wàá (910) kí ó tó kú.

15 Nígbà tí Mahalaleli di ẹni ọdún marundinlaadọrin, ó bí Jaredi.

16 Lẹ́yìn tí ó bí Jaredi, ó gbé ẹgbẹrin ọdún ó lé ọgbọ̀n (830) láyé, ó sì bí àwọn ọmọ mìíràn lọkunrin ati lobinrin.

17 Gbogbo ọdún tí Mahalaleli gbé láyé jẹ́ ẹẹdẹgbẹrun ọdún ó dín marun-un (895) kí ó tó kú.

18 Nígbà tí Jaredi di ẹni ọdún mejilelọgọjọ (162) ó bí Enọku.

19 Lẹ́yìn tí ó bí Enọku, ó gbé ẹgbẹrin (800) ọdún láyé, ó sì bí àwọn ọmọ mìíràn lọkunrin ati lobinrin.

20 Gbogbo ọdún tí Jaredi gbé láyé jẹ́ ẹẹdẹgbẹrun ọdún ó lé mejilelọgọta (962) kí ó tó kú.

21 Nígbà tí Enọku di ẹni ọdún marundinlaadọrin ó bí Metusela.

22 Lẹ́yìn tí ó bí Metusela, ó wà ní ìrẹ́pọ̀ pẹlu Ọlọrun fún ọọdunrun (300) ọdún, ó sì bí àwọn ọmọ mìíràn lọkunrin ati lobinrin.

23 Gbogbo ọdún tí Enọku gbé láyé jẹ́ ọọdunrun ọdún ó lé marundinlaadọrin (365).

24 Enọku wà ní ìrẹ́pọ̀ pẹlu Ọlọrun, nígbà tí ó yá, wọn kò rí i mọ́ nítorí pé Ọlọrun mú un lọ.

25 Nígbà tí Metusela di ẹni ọgọsan-an ọdún ó lé meje (187) ó bí Lamẹki.

26 Lẹ́yìn tí ó bí Lamẹki, ó gbé ẹẹdẹgbẹrin ọdún ó lé mejilelọgọrin (782) sí i láyé, ó sì bí àwọn ọmọ mìíràn lọkunrin ati lobinrin.

27 Gbogbo ọdún tí Metusela gbé láyé jẹ́ ẹẹdẹgbẹrun ọdún ó lé mọkandinlaadọrin (969) kí ó tó kú.

28 Nígbà tí Lamẹki di ẹni ọdún mejilelọgọsan-an (182), ó bí ọmọkunrin kan.

29 Ó sọ ọ́ ní Noa, ó ní: “Eléyìí ni yóo mú ìtura wá fún wa ninu iṣẹ́ ati wahala wa tí à ń ṣe lórí ilẹ̀ tí OLUWA ti fi gégùn-ún.”

30 Lẹ́yìn tí Lamẹki bí Noa, ó gbé ọdún marundinlẹgbẹta (595) láyé, ó sì bí àwọn ọmọ mìíràn lọkunrin ati lobinrin.

31 Gbogbo ọdún tí Lamẹki gbé láyé jẹ́ ẹẹdẹgbẹrin ọdún ó lé mẹtadinlọgọrin (777) kí ó tó kú.

32 Nígbà tí Noa di ẹni ẹẹdẹgbẹta (500) ọdún, ó bí Ṣemu, Hamu ati Jafẹti.

Categories
JẸNẸSISI

JẸNẸSISI 6

Ìwà Burúkú Eniyan

1 Nígbà tí eniyan bẹ̀rẹ̀ sí pọ̀ sí i lórí ilẹ̀, tí wọ́n sì ń bí ọmọbinrin,

2 nígbà náà ni àwọn ẹ̀dá ọ̀run lọkunrin ṣe akiyesi pé àwọn ọmọbinrin tí eniyan ń bí lẹ́wà gidigidi, wọ́n sì bẹ̀rẹ̀ sí fẹ́ èyí tí ó wù wọ́n lára wọn.

3 OLUWA bá wí pé, “N kò ní jẹ́ kí eniyan wà láàyè títí lae, nítorí pé ẹlẹ́ran ara ni wọ́n. Ọgọfa (120) ọdún ni wọn yóo máa gbé láyé.”

4 Àwọn òmìrán wà láyé ní ayé ìgbà náà, wọ́n tilẹ̀ tún wà láyé fún àkókò kan lẹ́yìn rẹ̀. Nígbà tí àwọn ọmọkunrin Ọlọrun fẹ́ aya láàrin àwọn ọmọ eniyan, àwọn ọmọ tí wọ́n bí ni àwọn òmìrán wọnyi. Àwọn ni wọ́n jẹ́ akọni ati olókìkí nígbà náà.

5 Nígbà tí OLUWA rí i pé ìwà burúkú eniyan ti pọ̀ jù láyé, ati pé kìkì ibi ni èrò inú wọn nígbà gbogbo,

6 inú rẹ̀ bàjẹ́ gidigidi pé ó dá eniyan sí ayé, ó sì dùn ún,

7 tóbẹ́ẹ̀ tí ó fi wí pé, “N óo pa àwọn ẹ̀dá alààyè tí mo dá run lórí ilẹ̀ ayé, ati eniyan ati ẹranko ati àwọn ohun tí ń fàyà fà káàkiri lórí ilẹ̀, ati ẹyẹ, gbogbo wọn ni n óo parun, nítorí ó bà mí ninu jẹ́ pé mo dá wọn.”

8 Ṣugbọn Noa rí ojurere OLUWA.

Ìtàn Noa

9 Ìtàn ìran Noa nìyí: Noa jẹ́ olódodo, òun nìkan ṣoṣo ni eniyan pípé ní àkókò tirẹ̀, ó sì wà ní ìrẹ́pọ̀ pẹlu OLUWA.

10 Ó bí ọmọkunrin mẹta tí orúkọ wọn ń jẹ́ Ṣemu, Hamu, ati Jafẹti.

11 Ayé kún fún ìwà ìbàjẹ́ lójú Ọlọrun, ìwà jàgídíjàgan sì gba gbogbo ayé.

12 Ọlọrun rí i pé ayé ti bàjẹ́, nítorí pé ìwà ìbàjẹ́ ni gbogbo eniyan ń hù.

13 Ọlọrun bá sọ fún Noa pé, “Mo ti pinnu láti pa gbogbo ẹ̀dá alààyè run, nítorí ìwà ipá wọn ti gba gbogbo ayé, àtàwọn àtayé ni n óo parun.

14 Nítorí náà, fi igi goferi kan ọkọ̀ ojú omi fún ara rẹ. Ṣe ọpọlọpọ yàrá sinu rẹ̀, kí o sì fi ọ̀dà kùn ún ninu ati lóde.

15 Bí o óo ti kan ọkọ̀ náà nìyí: kí gígùn rẹ̀ jẹ́ ọọdunrun (300) igbọnwọ, ìbú rẹ̀ yóo jẹ́ aadọta igbọnwọ, gíga rẹ̀ yóo jẹ́ ọgbọ̀n igbọnwọ.

16 Kan òrùlé sí orí ọkọ̀ náà, ṣugbọn fi ààyè sílẹ̀ láàrin orí rẹ̀ ati ẹ̀gbẹ́ rẹ̀ yíká, tí yóo jẹ́ ìwọ̀n igbọnwọ kan. Kí o kan ọkọ̀ náà ní ìpele mẹta, kí o sì ṣe ẹnu ọ̀nà sí ẹ̀gbẹ́ rẹ̀.

17 N óo jẹ́ kí ìkún omi bo gbogbo ayé, yóo pa gbogbo ẹ̀dá alààyè run, gbogbo ohun ẹlẹ́mìí tí ó wà láyé ni yóo kú.

18 Ṣugbọn n óo bá ọ dá majẹmu, o óo wọ inú ọkọ̀ náà, ìwọ pẹlu aya rẹ ati àwọn ọmọkunrin rẹ ati àwọn aya wọn.

19 Kí o sì mú meji meji ninu gbogbo ohun alààyè, kí wọ́n lè wà láàyè pẹlu rẹ, takọ-tabo ni kí o mú wọn.

20 Meji meji yóo tọ̀ ọ́ wá ninu oríṣìíríṣìí àwọn ẹyẹ, ati oríṣìíríṣìí àwọn ẹran ọ̀sìn, ati oríṣìíríṣìí àwọn ohun tí ń fàyà fà lórí ilẹ̀, kí o lè mú kí wọ́n wà láàyè pẹlu rẹ.

21 Kí o sì kó oniruuru oúnjẹ sinu ọkọ̀ náà fún ara rẹ ati fún wọn.”

22 Noa bá ṣe gbogbo ohun tí Ọlọrun pàṣẹ fún un.

Categories
JẸNẸSISI

JẸNẸSISI 7

Ìkún Omi

1 Nígbà tí ó yá OLUWA sọ fún Noa pé, “Wọ inú ọkọ̀ lọ, ìwọ ati àwọn ará ilé rẹ, nítorí pé ìwọ nìkan ni o jẹ́ olódodo sí mi ní gbogbo ayé.

2 Ninu gbogbo ẹran tí ó bá jẹ́ mímọ́, mú wọn ní takọ-tabo, meje meje, ṣugbọn ninu gbogbo ẹran tí kò bá jẹ́ mímọ́, mú akọ kan ati abo kan.

3 Mú takọ-tabo meje meje ninu àwọn ẹyẹ, kí irú wọn lè wà láàyè lórí ilẹ̀ ayé.

4 Nítorí pé ọjọ́ meje ló kù tí n óo bẹ̀rẹ̀ sí rọ òjò sórí ilẹ̀ fún ogoji ọjọ́ tọ̀sán-tòru, gbogbo ẹ̀dá alààyè tí mo dá ni yóo sì parun lórí ilẹ̀ ayé.”

5 Noa bá ṣe gbogbo ohun tí OLUWA pa láṣẹ fún un.

6 Noa jẹ́ ẹni ẹgbẹta (600) ọdún nígbà tí ìkún omi bo ilẹ̀ ayé.

7 Noa wọ inú ọkọ̀ lọ, òun ati aya rẹ̀ ati àwọn ọmọ rẹ̀ pẹlu aya wọn, láti sá àsálà kúrò lọ́wọ́ ìkún omi.

8 Gbogbo ẹran ati àwọn tí wọ́n mọ́ ati àwọn tí wọn kò mọ́, àwọn ẹyẹ ati gbogbo ohun tí ń fàyà fà lórí ilẹ̀,

9 ní meji meji, àtakọ àtabo, gbogbo wọn bá Noa wọ inú ọkọ̀ gẹ́gẹ́ bí Ọlọrun ti pa á láṣẹ fún Noa.

10 Lẹ́yìn ọjọ́ keje, ìkún omi bo ilẹ̀ ayé.

11 Ní ọjọ́ kẹtadinlogun oṣù keji ọdún tí Noa di ẹni ẹgbẹta (600) ọdún, ni orísun alagbalúgbú omi tí ó wà ninu ọ̀gbun ńlá lábẹ́ ilẹ̀ ya, tí gbogbo fèrèsé omi tí ó wà ní ojú ọ̀run ṣí sílẹ̀,

12 òjò sì rọ̀ fún ogoji ọjọ́, tọ̀sán-tòru.

13 Ní ọjọ́ náà gan-an ni Noa wọ inú ọkọ̀ lọ, òun ati àwọn ọmọ rẹ̀ mẹtẹẹta, Ṣemu, Hamu, ati Jafẹti ati aya rẹ̀ ati àwọn aya àwọn ọmọ rẹ̀ mẹtẹẹta;

14 pẹlu àwọn ẹranko ati àwọn ẹran ọ̀sìn, ati àwọn ohun tí ń fàyà fà káàkiri lórí ilẹ̀, ati oniruuru àwọn ẹyẹ.

15 Gbogbo àwọn ẹ̀dá alààyè patapata ni wọ́n wọ inú ọkọ̀ tọ Noa lọ ní meji meji.

16 Gbogbo àwọn ohun ẹlẹ́mìí, akọ kan, abo kan, ní oríṣìí kọ̀ọ̀kan wọlé gẹ́gẹ́ bí Ọlọrun ti pàṣẹ fún Noa. OLUWA bá ti ìlẹ̀kùn ọkọ̀ náà.

17 Ìkún omi wà lórí ilẹ̀ fún ogoji ọjọ́. Omi náà pọ̀ tóbẹ́ẹ̀ tí ọkọ̀ fi léfòó lójú omi.

18 Bí omi náà ti ń pọ̀ sí i ni ọkọ̀ náà ń lọ síhìn-ín sọ́hùn-ún lórí rẹ̀.

19 Omi náà pọ̀ tóbẹ́ẹ̀ tí ó fi bo gbogbo àwọn òkè gíga tí wọ́n wà láyé mọ́lẹ̀.

20 Ó sì tún pọ̀ sí i títí tí ó fi ga ju àwọn òkè gíga lọ ní igbọnwọ mẹẹdogun (mita 7).

21 Gbogbo àwọn ẹ̀dá alààyè tí wọ́n wà lórí ilẹ̀ ayé ni wọ́n kú patapata, ati ẹyẹ, ati ẹran ọ̀sìn, ati ẹranko, ati àwọn ohun tí wọn ń fàyà fà ati eniyan.

22 Gbogbo ẹ̀dá alààyè tí ń mí lórí ilẹ̀ ayé patapata ni wọ́n kú.

23 Bẹ́ẹ̀ ni OLUWA ṣe pa gbogbo ẹ̀dá alààyè tí ó wà láyé run: gbogbo eniyan, gbogbo ẹranko, gbogbo ohun tí ń rìn káàkiri lórí ilẹ̀ ati ẹyẹ. Noa nìkan ni kò kú ati àwọn tí wọ́n jọ wà ninu ọkọ̀ pẹlu rẹ̀.

24 Aadọjọ (150) ọjọ́ gbáko ni omi fi bo gbogbo ilẹ̀.

Categories
JẸNẸSISI

JẸNẸSISI 8

Ìkún Omi Gbẹ

1 Ṣugbọn Ọlọrun ranti Noa, ati gbogbo ẹranko, ati ẹran ọ̀sìn tí ó wà pẹlu rẹ̀ ninu ọkọ̀. Nítorí náà, Ọlọrun mú kí afẹ́fẹ́ kan fẹ́ sórí ilẹ̀, omi náà sì bẹ̀rẹ̀ sí fà.

2 Ọlọrun sé orísun omi tí ó wà lábẹ́ ilẹ̀, ó ti àwọn fèrèsé ojú ọ̀run, òjò náà sì dá.

3 Omi bá bẹ̀rẹ̀ sí fà lórí ilẹ̀. Lẹ́yìn aadọjọ (150) ọjọ́, omi náà fà tán.

4 Ní ọjọ́ kẹtadinlogun oṣù keje, ìdí ọkọ̀ náà kanlẹ̀ lórí òkè Ararati.

5 Omi náà sì ń fà sí i títí di oṣù kẹwaa. Ní ọjọ́ kinni oṣù náà ni ṣóńṣó orí àwọn òkè ńlá hàn síta.

6 Lẹ́yìn ogoji ọjọ́, Noa ṣí fèrèsé ọkọ̀ tí ó kàn.

7 Ó rán ẹyẹ ìwò kan jáde. Ẹyẹ yìí bẹ̀rẹ̀ sí fò káàkiri títí tí omi fi gbẹ lórí ilẹ̀.

8 Ó tún rán ẹyẹ àdàbà kan jáde láti lọ wò ó bóyá omi ti gbẹ lórí ilẹ̀,

9 ṣugbọn àdàbà náà kò rí ibi tí ó lè bà sí nítorí pé omi bo gbogbo ilẹ̀, ó bá fò pada tọ Noa lọ ninu ọkọ̀. Noa na ọwọ́ jáde láti inú ọkọ̀, ó sì mú un wọlé.

10 Ó dúró fún ọjọ́ meje kí ó tó tún rán àdàbà náà jáde.

11 Àdàbà náà fò pada ní ìrọ̀lẹ́ ọjọ́ náà pẹlu ewé olifi tútù ní ẹnu rẹ̀, bẹ́ẹ̀ ni Noa ṣe mọ̀ pé omi ti fà lórí ilẹ̀.

12 Ó tún dúró fún ọjọ́ meje sí i, lẹ́yìn náà, ó tún rán àdàbà náà jáde, ṣugbọn àdàbà náà kò pada sọ́dọ̀ Noa mọ́.

13 Ní ọjọ́ kinni oṣù kinni ọdún tí Noa di ẹni ọdún mọkanlelẹgbẹta (601), omi gbẹ tán lórí ilẹ̀. Noa ṣí òrùlé ọkọ̀, ó yọjú wo ìta, ó sì rí i pé ilẹ̀ ti gbẹ.

14 Ní ọjọ́ kẹtadinlọgbọn oṣù keji ni ilẹ̀ gbẹ tán patapata.

15 Ọlọrun sọ fún Noa pé,

16 “Jáde kúrò ninu ọkọ̀, ìwọ ati aya rẹ, ati àwọn ọmọ rẹ, ati àwọn aya wọn.

17 Kó gbogbo ẹ̀dá alààyè tí ó wà pẹlu rẹ jáde, àwọn ẹyẹ, ẹranko ati àwọn ohun tí ń fàyà fà lórí ilẹ̀, kí wọ́n lè máa bímọ lémọ, kí wọ́n sì pọ̀ sí i lórí ilẹ̀ ayé.”

18 Noa bá jáde kúrò ninu ọkọ̀, òun ati aya rẹ̀, ati àwọn ọmọ rẹ̀, ati àwọn aya wọn,

19 pẹlu gbogbo àwọn ẹranko, gbogbo àwọn ohun tí ń rìn káàkiri lórí ilẹ̀ ati àwọn ẹyẹ. Gbogbo àwọn ohun tí ń rìn káàkiri lórí ilẹ̀ patapata ni wọ́n bá Noa jáde kúrò ninu ọkọ̀.

Noa Rúbọ

20 Noa tẹ́ pẹpẹ kan fún OLUWA, ó mú ọ̀kọ̀ọ̀kan ninu àwọn ẹran ati àwọn ẹyẹ tí wọ́n mọ́, ó fi wọ́n rúbọ lórí pẹpẹ náà.

21 Nígbà tí OLUWA gbọ́ òórùn dídùn ẹbọ náà, ó wí ninu ara rẹ̀ pé, “N kò ní fi ilẹ̀ gégùn-ún mọ́ nítorí eniyan, nítorí pé, láti ìgbà èwe wọn wá ni èrò inú wọn ti jẹ́ kìkì ibi. Bẹ́ẹ̀ ni n kò ní pa gbogbo ẹ̀dá alààyè run mọ́ bí mo ti ṣe yìí.

22 Níwọ̀n ìgbà tí ayé bá ṣì wà, ìgbà gbígbìn ati ìgbà ìkórè kò ní ṣàìwà, bẹ́ẹ̀ náà ni ìgbà òtútù ati ìgbà ooru, ìgbà òjò ati ìgbà ẹ̀ẹ̀rùn yóo sì máa wà pẹlu.”

Categories
JẸNẸSISI

JẸNẸSISI 9

Ọlọrun Bá Noa Dá Majẹmu

1 Ọlọrun súre fún Noa ati àwọn ọmọ rẹ̀, ó ní, “Ẹ máa bímọ lémọ, kí ẹ máa pọ̀ sí i, kí ẹ sì kún gbogbo ayé.

2 Gbogbo ẹranko tí ó wà láyé, gbogbo ẹyẹ, gbogbo ẹja tí ń bẹ ninu omi, ati gbogbo ohun tí ń rìn káàkiri ni yóo máa bẹ̀rù yín, ìkáwọ́ yín ni mo fi gbogbo wọn sí.

3 Gbogbo ohun alààyè tí ń rìn ni yóo jẹ́ oúnjẹ fún yín, bí mo ti fún yín ní gbogbo ewéko, bẹ́ẹ̀ náà ni mo fún yín ní ohun gbogbo.

4 Ṣugbọn ẹ kò gbọdọ̀ jẹ ẹran ti òun ti ẹ̀jẹ̀, nítorí pé, ninu ẹ̀jẹ̀ ni ìyè wà.

5 Dájúdájú n óo gbẹ̀san lára ẹnikẹ́ni tí ó bá paniyan, kì báà jẹ́ ẹranko ni ó paniyan tabi eniyan ni ó pa ẹlẹgbẹ́ rẹ̀, pípa ni a óo pa olúwarẹ̀.

6 Ẹnikẹ́ni tí ó bá paniyan, pípa ni a óo pa òun náà, nítorí pé ní àwòrán Ọlọrun fúnrarẹ̀ ni ó dá eniyan.

7 “Ẹ máa bímọ lémọ, kí ẹ máa pọ̀ sí i, kí ẹ sì kún gbogbo ayé.”

8 Lẹ́yìn náà Ọlọrun sọ fún Noa ati àwọn ọmọ rẹ̀ pé,

9 “Wò ó! Mo bá ẹ̀yin ati atọmọdọmọ yín dá majẹmu, ati gbogbo ẹ̀dá alààyè tí wọ́n wà pẹlu yín:

10 Gbogbo àwọn ẹyẹ, àwọn ẹran ọ̀sìn ati àwọn ẹranko tí wọ́n bá yín jáde ninu ọkọ̀,

11 majẹmu náà ni pé, lae, n kò tún ní fi ìkún omi pa gbogbo ẹ̀dá alààyè run mọ́, bẹ́ẹ̀ ni kò ní sí ìkún omi tí yóo pa ayé rẹ́ mọ́.

12 Ohun tí yóo jẹ́ àmì majẹmu tí mo ń bá ẹ̀yin ati gbogbo ẹ̀dá alààyè dá, tí yóo sì wà fún atọmọdọmọ yín ní ọjọ́ iwájú nìyí:

13 mo fi òṣùmàrè mi sí ojú ọ̀run, òun ni yóo máa jẹ́ àmì majẹmu tí mo bá ayé dá.

14 Nígbàkúùgbà tí mo bá mú kí òjò ṣú ní ojú ọ̀run, tí òṣùmàrè bá sì yọ jáde,

15 n óo ranti majẹmu tí mo bá ẹ̀yin ati gbogbo ẹ̀dá alààyè dá pé, omi kò ní kún débi pé yóo pa ayé rẹ́ mọ́.

16 Nígbà tí òṣùmàrè bá yọ, n óo wò ó, n óo sì ranti majẹmu ayérayé tí èmi Ọlọrun bá gbogbo ẹ̀dá alààyè tí ó wà láyé dá.

17 Èyí ni majẹmu tí mo bá gbogbo ẹ̀dá alààyè tí ó wà láyé dá.”

Noa ati Àwọn Ọmọkunrin Rẹ̀

18 Àwọn ọmọ Noa tí wọ́n jáde ninu ọkọ̀ ni: Ṣemu, Hamu ati Jafẹti. Hamu ni ó bí Kenaani.

19 Àwọn ọmọ Noa mẹtẹẹta yìí ni baba ńlá gbogbo ayé.

20 Noa ni ẹni kinni tí ó kọ́kọ́ ṣe iṣẹ́ àgbẹ̀, tí ó gbin ọgbà àjàrà.

21 Noa mu àmupara ninu ọtí waini ọgbà rẹ̀, ó sì sùn sinu àgọ́ rẹ̀ ní ìhòòhò.

22 Hamu, baba Kenaani, rí baba rẹ̀ ní ìhòòhò, ó lọ sọ fún àwọn arakunrin rẹ̀ mejeeji lóde.

23 Ṣemu ati Jafẹti bá mú aṣọ kan, wọ́n fà á kọ́ èjìká wọn, wọ́n fi ẹ̀yìn rìn lọ sí ibi tí baba wọn sùn sí, wọ́n sì dà á bò ó, wọ́n kọ ojú sí ẹ̀gbẹ́ kan, wọn kò sì rí ìhòòhò baba wọn.

24 Nígbà tí ọtí dá lójú Noa, tí ó gbọ́ ohun tí àbíkẹ́yìn rẹ̀ ṣe sí i,

25 Ó ní,

“Ẹni ègún ni Kenaani,

ẹrú lásánlàsàn ni yóo jẹ́ fún àwọn arakunrin rẹ̀.”

26 Ó tún fi kún un pé,

“Kí OLUWA Ọlọrun mi bukun Ṣemu,

ẹrú rẹ̀ ni Kenaani yóo máa ṣe.

27 Kí Ọlọrun sọ ìdílé Jafẹti di pupọ,

kí ó máa gbé ninu àgọ́ Ṣemu,

ẹrú rẹ̀ ni Kenaani yóo máa ṣe.”

28 Ọọdunrun ọdún ó lé aadọta (350) ni Noa tún gbé sí i lẹ́yìn ìkún omi.

29 Noa kú nígbà tí ó di ẹni ẹgbẹrun ọdún ó dín aadọta (950).